Yoruba NationYoruba Nation One million man march: Àwọn tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation ní IPOB kò ṣiṣẹ pọ̀ pẹ̀lú àwọn
Àwọn to n ṣagbatẹru idasilẹ Yoruba nation ti ṣalaye fun ijọba Naijiria pe ẹgbẹ ajijagbara IPOB kọ lo ṣe agbekalẹ ifẹhonuhan tawọn n ṣe ni olu ileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN lorilẹede Amẹrika. Eyi ni esi wọn si atẹjade ijọba apapọ to kilọ pe wọn o gbọdọ ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra, IPOB. Lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii lawọn ajijagbara fun Yoruba Nation atawọn ẹya mii naa ni Naijiria ti n ṣe iwọde ni olu ileeṣẹ ajọ UN niluu New York lorilẹede Amẹrika. Iwọde yii wa jẹ asiko kan naa pẹlu apejọ ajọ UN nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn olori orilẹede agbaye mii yoo ti sọrọ apilẹkọ. Alaga ẹgbẹ NINAS to jẹ akojọpọ awọn ẹgbẹ ajijagbara ni Naijiria, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni awọn n ṣe iwọde niwaju olu ileeṣẹ ajọ UN lati le jẹki gbogbo aye mọ bi awọn darandaran ṣe n fi ẹmi awọn eeyan ṣofo lapa Guusu ati arin gbungbun orilẹede Naijiria Ijoba Naijiria ni idi ti awọn se n lọgun bẹẹ ni pe labẹ ofin awọn ka IPOB gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi to n da omi a...