Yoruba NationYoruba Nation One million man march: Àwọn tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation ní IPOB kò ṣiṣẹ pọ̀ pẹ̀lú àwọn



 Àwọn to n ṣagbatẹru idasilẹ Yoruba nation ti ṣalaye fun ijọba Naijiria pe ẹgbẹ ajijagbara IPOB kọ lo ṣe agbekalẹ ifẹhonuhan tawọn n ṣe ni olu ileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN lorilẹede Amẹrika.

Eyi ni esi wọn si atẹjade ijọba apapọ to kilọ pe wọn o gbọdọ ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra, IPOB.

Lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii lawọn ajijagbara fun Yoruba Nation atawọn ẹya mii naa ni Naijiria ti n ṣe iwọde ni olu ileeṣẹ ajọ UN niluu New York lorilẹede Amẹrika.

Iwọde yii wa jẹ asiko kan naa pẹlu apejọ ajọ UN nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn olori orilẹede agbaye mii yoo ti sọrọ apilẹkọ.

Alaga ẹgbẹ NINAS to jẹ akojọpọ awọn ẹgbẹ ajijagbara ni Naijiria, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni awọn n ṣe iwọde niwaju olu ileeṣẹ ajọ UN lati le jẹki gbogbo aye mọ bi awọn darandaran ṣe n fi ẹmi awọn eeyan ṣofo lapa Guusu ati arin gbungbun orilẹede Naijiria

Ijoba Naijiria ni idi ti awọn se n lọgun bẹẹ ni pe labẹ ofin awọn ka IPOB gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi to n da omi alafiaa ru.

Ninu atẹjade kan lati ọwọ oludamọran agba si aarẹ, Garba Shehu, o ni IPOB ni to awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna aadọta ọmọ ogun ti rẹ.

O fi kun un pe ko si ẹni ti yoo ka awọn to n beere fun idasilẹ Yoruba Nation kun lopin igba ti wọn ba n ba n ṣe iwọde to mu iwa janduku lọwọ.

Ọrọ́ ileesẹ aarẹ yi ko sẹyin bi awọn ọmọ ikọ IPOB se darapọ mọ awọn ti Yoruba Nation nibi iwọde ranpẹ ti wọn se niwaju ẹgbẹ isọkan agbaye ni New York.

Nibi iwọde yi ni wọn ti fi ẹhonu han lori awọn aiṣedeede to n waye ni Naijiria ati ipe wọn fun idasilẹ orileede Yoruba Nation…. (Yoruba Nation One million man march: Àwọn tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation ní IPOB kò ṣiṣẹ pọ̀ pẹ̀lú àwọn - BBC News Yorùbá)

 

 


Comentários

Postagens mais visitadas deste blog

Ẹ kaabọ̀ si Kilombo Kingoma náà, akọkọ ilẹ̀ ibilẹ̀ Afirika ni okeere

Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa keji

Ògún Lakaye Osìn imọlẹ̀