Oba Lamidi Adeyemi ti jáde láyé!
BBC Yoruba ti kan si Aafin Oyo fun ẹkunrẹrẹ lori iku Ọba Lamidi Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo. Iroyin naa tẹ wa lọwọ ni yajoyajo lowurọ yii to sọ pe Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti lọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ lajule ọrun. "Gbogbo eto aṣa ati iṣẹẹṣe ti bẹrẹ bayii ni Aafin"! Ki lo n ṣẹlẹ l'Aafin Alaafin lọwọ lowurọ yii? Ọmọba ni Aafin Oyo sọ fun BBC Yoruba pe kete ti wọn rii pe baba ti re alakeji ni ilana aṣa ati iṣẹṣe ti bẹrẹ l'Aafin ni pẹrẹwu. "Wọn ti bẹrẹ aṣa ati iṣẹṣe bayii. A ni ki ni yoo tun ṣẹlẹ bi ojumọ ba ti mọ ni Aafin, ọmọba ni "ṣe ẹ mọ pe ọmọde lemi, awọn agbaagba si wa atawọn alaṣẹ ni Aafin torinaa emi o le sọ". Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà Ni oru ọganjọ ti a kọkọ bẹrẹ si ni gbọ fiinfiin ni BBC Yoruba ti tara ṣaṣa kan si afin ti ọkan lara awọn ọmọ aafin rẹ si fi da wa loju pe Baba ti lọ. Wiwadii yii kan ṣe kongẹ asiko ti ọmọ wọn maa n ji fun saari, ni ...