Oba Lamidi Adeyemi ti jáde láyé!
BBC Yoruba ti kan si Aafin Oyo fun ẹkunrẹrẹ lori iku Ọba Lamidi
Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo.
Iroyin naa tẹ wa lọwọ ni
yajoyajo lowurọ yii to sọ pe Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti lọ
darapọ mọ awọn baba nla rẹ lajule ọrun.
"Gbogbo eto aṣa ati iṣẹẹṣe ti bẹrẹ bayii ni Aafin"!
Ki lo n ṣẹlẹ l'Aafin Alaafin lọwọ lowurọ yii?
Ọmọba ni Aafin Oyo sọ fun BBC Yoruba pe kete ti wọn rii pe baba
ti re alakeji ni ilana aṣa ati iṣẹṣe ti bẹrẹ l'Aafin ni pẹrẹwu.
"Wọn ti bẹrẹ aṣa ati
iṣẹṣe bayii. A ni ki ni yoo tun ṣẹlẹ bi ojumọ ba ti mọ ni Aafin, ọmọba ni
"ṣe ẹ mọ pe ọmọde lemi, awọn agbaagba si wa atawọn alaṣẹ ni Aafin torinaa
emi o le sọ".
Wo àwọn ǹkan tí
o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
Ni oru ọganjọ ti a kọkọ
bẹrẹ si ni gbọ fiinfiin ni BBC Yoruba ti tara ṣaṣa kan si afin ti ọkan lara
awọn ọmọ aafin rẹ si fi da wa loju pe Baba ti lọ. Wiwadii yii kan ṣe kongẹ
asiko ti ọmọ wọn maa n ji fun saari, ni to si jẹ anfani fun BBC Yoruba tori
ibaṣepọ oun ati ẹni to ba sọrọ lara wa amọ ti a ko le darukọ ẹnikẹni.
Nigba ti BBC Yoruba ba ọkan lara awọn ọm Alaafin to ti wa laafin
lowurọ yii sọrọ o fi da wa loju pe lootọ ni Baba ti lọ.
"Bo ṣe ri gangan ni
iroyin tẹẹ gbọ yẹn, nkan tẹẹ gbọ yẹn naa ootọ ni. Baba ti lọ ni owurọ
yii".
Nigba ti a beere pe igba wo lo ṣẹlẹ gangan toripe awọn oniwe
iroyin kan ti n gbe e kiri pe alẹ ana ọjọ Ẹti ni Kabiyesi ku, ọmọba ni
"aarọ yii gangan lo ṣẹlẹ".
A o maa mu ẹkunrẹrẹ́ wa
fun yin bo ba ṣe n lọ.

Comentários
Postar um comentário