Jẹ́ ki a ranti Iya Olga Alaketu laarin Oṣu Keje ti Obinrin dúdú
Julho das Pretas náà, [Oṣu keje fún iranti ìtan àwọn obinrin aláw ọ̀ dúdú] jẹ́ ayẹyẹ kan ti wọ́n ṣeda ni ọdún 2013 nipasẹ àwọn ẹgbẹ ajijagbara fún àwọn ẹ̀tọ́ obinrin aláwọ̀ dúdú kaakiri oríllẹ̀-èdè náà, labẹ̀ oludari ẹgbẹ iṣẹ ajijagbara kan ti lorukọ ni “ODARA” Ni ọjọ́ 25, Oṣu Keje lọdọ̀ọ̀dún wọ́n yoo ṣe iranti àwọn obinrin dúdú ti Afro-Latin Amẹ́rika, ti Afro-Caribbean àti àwọn Obinrin dúdú ti orílẹ̀-èdè náà. Erongba ti ayẹyẹ náà ni ifọkansi lati mu àwọn èto ati ẹgbẹ ti ń ṣiṣẹ fún daabòbò àwọn ẹ̀tọ́ ọmọyian ti obinrin dúdú, lagbara fún idagbasoke ipo wọn ninu awujọ ìlú Burasili patapata. O ṣe pàtàkì pùpọ́ ti a maa bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn obinrin dúdú, paapaa jùlo àwọn ti o duro ni iṣẹ wọ́n laibikita àwọn aisedede iṣoro. Nitori eyi, jẹ́ ki a bọ̀wọ̀ fún Olori Íyálòrìṣà Olga Alaketu. Orukọ oyinbo ti Ìyálòrìṣà yìí ni Olga Francisca Régis ti gbogbo kaakiri orílẹ̀-èdè mọ sí Olga do Alaketu [Olga Alaketu]. Ṣùgbọ́...