Da Rocha: Ìlú Iléṣà ni bàbá miliọníà àkọ́kọ́ ti wá, àmọ́ ó ṣe ẹrú ní Brazil
Ni ọpọ igba, lawọn eeyan maa n ṣe apejuwe eeyan kan to ba ri
jajẹ ni awujọ pe ẹni naa lowo bii Da Rocha tabi pe o lowo ju Da Rocha lọ.
Fun ọpọ ọmọ ilẹ Yoruba to wa loke eepẹ loni, eti lasan ni wọn fi n gbọ orukọ Da Rocha, wọn ko mọ iru eeyan to jẹ, ti awọn miran tiẹ ro pe arosọ lasan ni, ati pe Da Rocha kii ṣe ọmọ ilẹ Yoruba rara.
Ṣugbọn akọsilẹ lati loju opo itakun agbaye taa ti ko iroyin yii jọ fi ye wa pe, lootọ ni Da Rocha gbe nilu Eko, o lowo lọwọ pupọ nigba aye rẹ, oun si laa lee pe ni Miliọnia akọkọ nil Yoruba.
A
gbọ pe Da Rocha ba owo nile ni, tori pe baba rẹ ni owo lọwọ, amọ ti Candido
funra rẹ ṣiṣẹ mo owo to ba nile.
Iroyin fi ye wa pe Da Rocha kọle, o kọ aasẹ silu Eko, to si ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe ilu Eko ni idagbasoke ati awọn ohun eelo amayedẹrun to yẹ nigba to fi wa loke eepẹ.
N jẹ taa wa ni Miliọnia akọkọ nilẹ Yoruba naa, Da Rocha?
Candido Da Rocha wa saye, o se aye loore, o fi owo rẹ mọ ẹbi ara, ọrẹ ati awọn ojulumọ, taa si lee pe ni olowo to n fi owo saanu laye igba tiẹ.
O lẹmi iwa ikora ẹni nijanu, to si korira irọ pipa.
Awọn abuda rere Da Rocha lo yẹ ki awa naa fi se awokọse rere, ka si tun jẹ ọmọ ti yoo sọ ọla di pupọ, dipo ka jẹ agboju logun ati akotileta
Lati BBC Yoruba News https://www.bbc.com/yoruba/afrika-46919309 (4 Agemo 2021)

Comentários
Postar um comentário