Jẹ́ ki a ranti Iya Olga Alaketu laarin Oṣu Keje ti Obinrin dúdú
Julho das Pretas náà, [Oṣu keje fún iranti ìtan àwọn obinrin aláwọ̀ dúdú] jẹ́ ayẹyẹ kan ti wọ́n ṣeda ni ọdún 2013 nipasẹ àwọn ẹgbẹ ajijagbara fún àwọn ẹ̀tọ́ obinrin aláwọ̀ dúdú kaakiri oríllẹ̀-èdè náà, labẹ̀ oludari ẹgbẹ iṣẹ ajijagbara kan ti lorukọ ni “ODARA”
Ni ọjọ́ 25, Oṣu Keje lọdọ̀ọ̀dún wọ́n yoo ṣe iranti àwọn obinrin dúdú ti Afro-Latin Amẹ́rika, ti Afro-Caribbean àti àwọn Obinrin dúdú ti orílẹ̀-èdè náà.
Erongba ti ayẹyẹ náà ni ifọkansi lati mu àwọn èto
ati ẹgbẹ ti ń ṣiṣẹ fún daabòbò àwọn ẹ̀tọ́ ọmọyian ti obinrin dúdú,
lagbara fún idagbasoke ipo wọn ninu awujọ ìlú Burasili patapata.
O ṣe pàtàkì pùpọ́ ti a maa bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn
obinrin dúdú, paapaa jùlo àwọn ti o duro ni iṣẹ wọ́n laibikita àwọn aisedede
iṣoro.
Nitori eyi, jẹ́ ki a bọ̀wọ̀
fún Olori Íyálòrìṣà Olga Alaketu.
Orukọ oyinbo ti Ìyálòrìṣà yìí ni Olga Francisca Régis ti gbogbo kaakiri orílẹ̀-èdè mọ sí Olga do Alaketu [Olga Alaketu]. Ṣùgbọ́n, Ọyafúnmi ni orukọ tirẹ̀ ni èdè ati àṣa abinibi ẹbi Ànàgó rẹ̀.
Olga do Alaketu o ti jẹ́ Ọbinrin dúdú kan ti a bi ni ìlú Salvador, Olu-ìlú ti ipinlẹ̀ Bahia ni Oṣu Kẹsan, Ọjọ́ 9, Ọdún 1925 [Ó lọ si pada ilé àwọn bàbá nlá wọ́n ti mgbé lọrún ni Oṣu Kẹsan Ọjọ́ 29, Ọdún 2005].
Ó ti jẹ́ olori Ìyálòrìṣà ẹsin ibilẹ Afrika [ẹsin òrìṣà náà ti a n pè ni Kadonbilẹ̀ (CANDOMBLÉ)] ni ilé ijọsin kan ti loruko “Ilé Maroialaji” ni adugbo Matatu de Brotas,
Laarin àwọn ọdún iṣẹ wọn, Ilé Maroialaji náà di olokiki kaakiri oirílẹ̀-èdè.
Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pè ni ipari ọrundun XVIII, lakoko àwọn ota ikolu lati ijọba Dahomey si ilẹ̀ ijọba Ketu, laarin ijọba Akibiohu, wọ́n ti ji gbe ọmọ ọmọ ọba náà meji,(obinrin ni àwọn mejeji), a mu wọ́n fi si ẹrú. Labẹ̀ òwò ẹrú, wọ́n tó fi wa si ìlú ti wọ́n ń pè ni Baííà (Ìlú Salavador náà) ni orilẹ̀-èdè Burasili.
Ìtan náà tún sọ fún wa wipé ọkan ninu àwọn
ọmo ọmọ yìí, ti orukọ rẹ̀ ni Otampe Ojarô, lẹhin ọdún mẹsan ti o ṣiṣẹ bi
iranṣẹ ilé ni ilé ẹbi oyinbo kan, ṣáájú ki ó dá Ilé Maroiálaji, oún
gba ominira funrarẹ̀.
Olga jẹ́ ọmọbinrin ti Dionísia Francisca Régis, ti o jẹ́ ọmọ ọmọ ti Otampe Ojarô, so, ajogunba idilé ọba Arô, si itẹ ti ijọba Ketu (ijọba kan laarin àwọn ijọba Yorubá ni aye atijọ́), bayi ninu agbegbe ti orílẹ̀-èdè Bẹnin, ni Iwọ-oorun Afirika.”..
Olga do Alaketu jẹ́ ẹlẹgun ti Òrìṣà Ọya,ti lo kẹyin
ninu àwọn oriṣa meje to lagbara jùlọ lagbaye (Eṣu, Ògún, Ọbatala, Yemọja, Ọsun,
Ṣango, Ọya)
Àwọn ọmọ ninu ẹbi rẹ ati àwọn ẹlẹsin ibilẹ òrìṣà ti a ba ara rẹ lara igbesi aye tirẹ̀, sọ wipe pé wọ́n yoo ranti Olga gẹgẹbi Ìyá rere ti ka fi de ran wọn lọwọ́ nigbagbogbo.
Wọn sọ ni afikun pe Ìyá Olga ni àwọn ìwà ipliẹ̀ meji ki o jẹ̀ ki gbogbo oludari ẹsin gbọdọ maa tẹle: suuru ati ọ̀kan
rere.
Ni ọdún 1997, àwọn alaṣẹ ti ijọba orilẹ̀-èdè Buarasili apapọ̀ ń fún un ni ẹbún pàtàkì nitori iṣẹ takutakun rẹ̀.
Lẹhin iku Olga, Jocelina Bispo ti o jẹ ọmọbinrin tirẹ̀ ti rọpo oun gẹgẹ bi Olori Ìyálòrìṣà ti Ilé Maroialaji.

Comentários
Postar um comentário