Postagens

Mostrando postagens de setembro, 2021

Èdè Ànàgó náà kò fi ni parun

Imagem
  Ẹ ku deedee asiko yìí, mo ki gbogbo ọmọ Oduduwa kaakiri agbaye Burasili ni orílẹ̀-èdè ni eyiti aláwọ̀ dúdú pọ́ jù agbaye lehin orilẹ̀-èdè Naijiria lọ.   Pùpọ́ ninu olugbe ti ilẹ̀ yìí wa bi ni idilé ti ọmọ Afirika. Boya nitori ipo yìí, díẹ̀ ninu èdè ati àsà ajogunba latodo àwọn bàbá nlá wa tabi ìyá nlá wa ń tẹ́siwaju  gidi lode oni.   O kere jù, èdè abinibi mẹ́ta lati atilẹ̀ba ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ń tẹ́siwaju lo ni ode oni ni ibatan ẹsin abinibi. Èdè Ànàgó jẹ́ ọkan laarin èdè wọ̀nyí Mo toro gafara lọwọ́ gbogbo yin, ọmọ ìyá aláwọ̀ dúdú, fún aise deede mi. Má binu si mi latari ohun ti mo yoo sọ, ṣùgbọ́n, laisi iyemeji, èdè Ànàgó, lẹyin èdè Pọtugi, ti ló kù ti wọn n sọ ju ni Orílẹ̀-èdè yìí.   Ni aye atijọ́, paapaa ni ìlú Salvador, ti o jẹ́ Olú-ìlú ipinlẹ̀ Baííà, èdè Ànàgó náà di gẹgẹ bi Língua Franca ti ọpọlọpọ ọmọ ilẹ̀ Afirika fún, laibikita ti ẹ̀yà ara wọn.  Ni ode oni a npe èdè Ànàgó bi èdè Yorùbá. Ṣe o mọ wipe nitori pàtàkì àṣà ati èdè Yorùbá,...

Ìdìtẹ̀ fún òmìnira látọwọ́ àwọn ọmọ ìlú Baííà

Imagem
Ọ̀kan nínú gbogbo àwọn àgbéká pàtàkì jùlọ fún òmìnira ilẹ̀ Bùràsíìlì, lákòókò tí orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ amúnisìn kan ti ijọba Pọ́túgààlì, j ẹ́ ọ́ tẹ̀ kan tí ó ti ṣelẹ̀ ní bí i ìparí ọ̀rúndún XVIII (1798 – 1799), ní ìlú Salvador , olú-ìlú ìpínlẹ̀ Baííà. Èyí ni ìtàn ní kúkúrú nípa ọ̀kan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi pàtàkì ni ìbátan pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn aláwọ̀ dúdú ní orílẹ̀-èdè yìí. Nítorí náà, ni oṣù kẹ́jọ, ọjọ́ kejìlá ọdún yìí ní ààyè ìta gbañgba kan náà níbi tí ìṣàkóso ìjọba amúnisìn Pọtugí ṣekú pa ẹlẹ́wọ̀n aláwọ̀ dúdú mẹ́rin ní ọdún 1798, méjì láàárín àwọn aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Baííà àti àwọn olùdarí dúdú láti àwọn oríṣiríṣi àwùjọ, darapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí àwọn akíkanjú mẹ́rin náà tí ó kú nígbà yẹn. Gbogbo wá ṣomijé lójú. Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ kọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà sílẹ̀ tí à ń pè ní “ìdìtẹ̀ látọwọ́ àwọn aránṣọ” (nítorí díẹ̀ nínú àwọn olùkópa j ẹ́ aránṣọ). Wọ́n tún ń pè é ní “ìdìtẹ̀ látọwọ́ àwọn ọmọ ìlú Baííà”. Lẹ́nu áìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀-ìtàn bẹ̀rẹ̀ síí pe àkànṣe ẹgb ẹ́ náà ní “ìṣọ̀tẹ̀ ìkarahun...