Èdè Ànàgó náà kò fi ni parun
Ẹ ku deedee asiko yìí, mo ki gbogbo ọmọ Oduduwa kaakiri agbaye
Burasili ni orílẹ̀-èdè ni eyiti aláwọ̀ dúdú pọ́ jù agbaye lehin orilẹ̀-èdè Naijiria lọ.
Pùpọ́ ninu olugbe ti ilẹ̀ yìí wa bi ni idilé ti ọmọ Afirika.
Boya nitori ipo yìí, díẹ̀ ninu èdè ati àsà ajogunba latodo àwọn bàbá nlá wa tabi ìyá nlá wa ń tẹ́siwaju gidi lode oni.
O kere jù, èdè abinibi mẹ́ta lati atilẹ̀ba ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ń tẹ́siwaju lo ni ode oni ni ibatan ẹsin abinibi. Èdè Ànàgó jẹ́ ọkan laarin èdè wọ̀nyí
Mo toro gafara lọwọ́ gbogbo yin, ọmọ ìyá aláwọ̀ dúdú, fún aise deede mi. Má binu si mi latari ohun ti mo yoo sọ, ṣùgbọ́n, laisi iyemeji, èdè Ànàgó, lẹyin èdè Pọtugi, ti ló kù ti wọn n sọ ju ni Orílẹ̀-èdè yìí.
Ni aye atijọ́, paapaa ni ìlú Salvador, ti o jẹ́ Olú-ìlú ipinlẹ̀ Baííà, èdè Ànàgó náà di gẹgẹ bi Língua Franca ti ọpọlọpọ ọmọ ilẹ̀ Afirika fún, laibikita ti ẹ̀yà ara wọn.
Ni ode oni a npe èdè Ànàgó bi èdè Yorùbá.
Ṣe o mọ wipe nitori pàtàkì àṣà ati èdè Yorùbá, ipinlẹ̀ Baííà o to yan gẹgẹbi Olú-ìlú Yorùbá fún gbogbo Ilẹ̀ Amẹ́rika? Bẹ̀ẹ́ ni, ni osù kefa ọdún 2018, Ooni ti Ile-Ifẹ Kabiyesi Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi II sabewo ìlú Burasili. Lara ni ipinlẹ̀ Baííà, ni ọjọ́ 10, oun funraraarẹ̀ ti o kede pe Ipinlẹ̀ náà ni yoo di Olu-ìlú Yorùbá fún agbaye Amẹ́rika pata pata.
So, jẹ ki a kọ́ àwọn ọmọ wa ní èdé àti àṣà Yorùbá.

Comentários
Postar um comentário