Ìdìtẹ̀ fún òmìnira látọwọ́ àwọn ọmọ ìlú Baííà
Ọ̀kan nínú gbogbo àwọn àgbéká pàtàkì jùlọ fún òmìnira
ilẹ̀ Bùràsíìlì, lákòókò tí orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ amúnisìn kan ti ijọba Pọ́túgààlì,
jẹ́ ọ́tẹ̀ kan tí
ó ti ṣelẹ̀ ní bí i ìparí ọ̀rúndún XVIII (1798 – 1799), ní ìlú Salvador, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Baííà.
Èyí ni ìtàn ní kúkúrú nípa ọ̀kan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi pàtàkì ni ìbátan
pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn aláwọ̀ dúdú ní orílẹ̀-èdè yìí.
Nítorí náà, ni oṣù kẹ́jọ, ọjọ́ kejìlá
ọdún yìí ní ààyè ìta gbañgba kan náà níbi tí ìṣàkóso ìjọba amúnisìn Pọtugí ṣekú
pa ẹlẹ́wọ̀n aláwọ̀ dúdú mẹ́rin ní ọdún 1798, méjì láàárín àwọn aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀
Baííà àti àwọn olùdarí dúdú láti àwọn oríṣiríṣi àwùjọ, darapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí
àwọn akíkanjú mẹ́rin náà tí ó kú nígbà yẹn.
Gbogbo wá ṣomijé lójú.
Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ kọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà sílẹ̀ tí
à ń pè ní “ìdìtẹ̀ látọwọ́ àwọn aránṣọ” (nítorí díẹ̀ nínú àwọn olùkópa jẹ́ aránṣọ). Wọ́n tún ń pè é ní “ìdìtẹ̀ látọwọ́ àwọn ọmọ ìlú
Baííà”. Lẹ́nu áìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀-ìtàn bẹ̀rẹ̀
síí pe àkànṣe ẹgbẹ́ náà ní “ìṣọ̀tẹ̀ ìkarahun”
nítorí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà wọ ẹ̀gbà ọrùn-ọwọ́ pẹlu ìkarahun kan láti ṣe ìdánimọ̀
ara wọn láàárín àwọn ènìyàn ní ibi gbañgba.
Ẹ lè má mọ̀, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Bùràsíìlì
wà lábẹ́ ètò ìjọba
Pọ́túgààlì láti ọdún 1500 títí di ọdún 1822, nígbà tí orílẹ̀-èdè yìí gba òmìnira
rẹ̀.
Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ wípè ètò ọrọ̀ ajé tí ó lo iṣẹ́
ẹrú ní ilẹ̀ Bùràsíìlì wà ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta lọ? Bẹ́ẹ̀ ni, làti ọgọ́rùn-ún ọdún ẹ̀kẹẹ̀dógún (ọ̀rúndún XV), nígbà tí ọba ti Pọ́túgààlì gba ilẹ̀ yìí láti ọwọ́ àwọn olùgbé
abínibí, títí di òpin ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún
(ọ̀rúndún XIX).
Ǹjẹ́
ẹ mọ̀ wípè
ètò ẹrú yìí ni ó jẹ́ ìdí gan-an tí wọ́n fi jí mílíọ̀nù márùn--ún àwọn ọmọ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú gbé, láti ilẹ̀ abínibí wọn lọ sí orílẹ̀-èdè yìí, ní eyítí àwọn òyìnbó Pọtugí tà wọ́n lẹ́rú ní àkókò yìí?
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ọdún
1549, jẹ́ ọjọ́ ìpilẹ̀ ìlú Salvador gẹ́gẹ́ bí olú ìlú ilẹ̀ Bùràsíìlì. Fún ìdí èyí, ìlú yìí jẹ́ olú-ìlú àkọ́kọ́ ti ilẹ̀ Bùràsíìlì, láti ọdún 1549 títí di ọdún
1763, kí ó tó kan Rio de Janeiro, láti 1763, nítorí àwọn aláṣẹ amúnisìn ti pinnu láti sún olú-ìlú
láti Salvador sí ìlú yẹn.
Ṣùgbọ́n, ìgbésẹ̀ yìí mú kí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn pọ̀ si, pàápàá láàárín
àwọn ènìyàn tí kìí ṣe ẹrú ní àwọn ipò kèkeré láwùjọ.
Láìsí
iyè méjì, nítorí ìlú Salvador kìí ṣe olú-ìlú orílẹ̀-èdè náà mọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwò fi
ìlú náà sílẹ̀, ó sì jẹ́ ìdí gan-an fún ìdínkù àwọn ohun ajé àti ìgbilẹ̀ ìṣòro fún gbogbo wọn.
Ọ̀kan nínú áwọn ìyọrísí èyí ni ìdínkù agbára rírà àwọn olùgbé,
èyítí ó ṣokùnfà àwọn ìṣòro ìṣàkóso, nítorí àìní díẹ̀ nínú àwọn oúnjẹ lápá kan,
àti owó-orí gíga tí ìjọba Pọ́túgààlì ń gbà, lápá kejì. Àpapọ̀ èyí ṣokùnfà àṣà ọ̀tẹ̀ káàkiri.
Ní ipò àwùjọ yìí ni ìdìtẹ̀ bú jáde lójijì.
Nítorí
ìdalẹ̀ ọ̀kan
nínú àwọn ọlọ̀tẹ̀, ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ, ọdún 1798, ìdìtẹ̀
náà forí sọlẹ̀, àwọn agbófinró ìlú Baííà lákòókò yẹn mú àwọn ọkùnrin mẹ́talélọ́gbọ̀n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láàárín àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, wọ́n sì mú wọn lọ sílé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìdalẹ̀.
Lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ̀nyi ni àwọn ẹrú mọ́kànlá, àwọn ọmọ-ogun mẹ́fà, àwọn
aránṣọ márùn-ún, oníṣowo kékeké
kan, ọ̀mọ̀lé kan, olùkọ́ kan, oníṣẹ́ abẹ kan, àti gbẹ́nàgbẹ́nà kan. Aláwọ̀ dúdú
mẹ́rin nínú wọn ni wọ́n dájọ́ ikú fún.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ní ọjọ́ kẹjọ oṣù
kọkànlá, ọdún 1799, àwọn aláṣẹ amúnisìn so wọ́n rọ̀ ní ibi gbòòrò gbañgba tí à ń pè ní Piedade
(àánú) Square ní àárín ìlú náà.
Àwọn orúkọ àti iṣẹ́ olúkálùkù àwọn akíkanjú náà ni:
1.
Ọmọ-ogun Lucas Dantas do Amorim Torres.
2.
Ọmọ-iṣẹ́
aránṣọ Manuel Faustino dos Santos Lira.
3.
Ọmọ ogun Luís Gonzaga das Virgens.
4.
Ògá aránṣọ João
de Deus Nascimento.
Nítorí àwọn àfojúsí nínú àwọn iyè inú wọn nípa ìmúkúrò
ètò ẹrú jẹ́ nǹkan
gidi pàtàkì ìjà yìí, ó yàtọ̀ sí ìdìtẹ̀ kan
tí a
kà sí bí i ìjà
òmìnira pàtàkì jùlọ ní ìgbàgbọ́ nínú àkọsílẹ̀-ìtàn orílẹ̀-èdè yìí.
Akiyesi:
Apilẹkọ yìí ti a kọ́ ni èdè
Yorùbá latọwọ́ Mawo Adelson de Brito, o jẹ́ didasilẹ ni atunṣe latọwọ́ Ojogbọ́n
Engineer Abiodun Jibona
Note:
This article was written originally by Mawo Adelson de Brito it was brillantily
edited by Professor Engineer Abiodun Jibona
Nota:
Este artigo foi escrito em iorubá por Mawo Adelson de Brito e editado pelo
professor Abiodun Jibona.
Imagem: https://mst.org.br/2019/11/21/pretas-e-pretos-entoemos-o-canto-da-emancipacao/
(acessado em 09/09/2021)

Comentários
Postar um comentário