Oni ni ajọdún ti Ọọni Ilé-Ifẹ̀ náá ikede ìlú Bahia gẹgẹbi Olú-ìlú Yorùbá ti gbogbo àwọn Amẹ́rikà
Lára abẹwo si orílẹ̀-èdè Brasíìlì
ni oṣù
keje, ọdún 2018, Ọọni ile-Ifẹ náà, Ọba
Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji ni:
“... àwọn ọmọ Yorùbá to wa kaakiri igun mẹrẹrin agbaye
ko gbọdọ sọ ami idanimọ wọn nu, nitori ọmọ iya kan naa ni gbogbo awọn ọmọ Oodua
bii Itsekiri, Edo, Ga, Anago, Igala, Lucumi, Tapa, ati Yoruba ti orisun wọn si
wa ni ilu Ile Ifẹ...”
Àwọn iran
ti àwọn Ànàgó ni ode oni ìlú Brasílì kò le lo èdè náà fún àwọn ohun iṣe ti
ojojumọ wọn. Sibẹsibẹ, àwọn orin, ijó, ìtan aye atijọ́, ounjẹ ati ẹ̀sin ń
ṣiṣe ni ọpọ àgbègbé kaakiri orílẹ̀-èdè náà.
“... àwọn ọmọ
Yorùbá to wa kaakiri igun mẹrẹrin agbaye ko gbọdọ sọ ami idanimọ wọn nu, nitori
ọmọ iya kan naa ni gbogbo awọn ọmọ Oodua bii Itsekiri, Edo, Ga, Anago, Igala,
Lucumi, Tapa, ati Yoruba ti orisun wọn si wa ni ilu Ile Ifẹ...”
Àwọn iran
ti àwọn Ànàgó ni ode oni ìlú Brasílì kò le lo èdè náà fún àwọn ohun iṣe ti
ojojumọ wọn. Sibẹsibẹ, àwọn orin, ijó, ìtan aye atijọ́, ounjẹ ati ẹ̀sin ń
ṣiṣe ni ọpọ àgbègbé kaakiri orílẹ̀-èdè náà.
Gẹgẹbi àwọn ọmọ ìyá kan ṣoṣo, jẹ́ ki a ń ṣiṣẹ láti gbe àṣà wa larugẹ kaakiri àwon origun mẹrẹrin agbaye, pàápàá ni àwọn ìlú ni apa ila Gúsù Améríka àti Erékùṣù Karibian, nibi ti wọ́n ń tẹsiwaju gidigidi àṣà àti ẹ̀sin òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.
Ni ọjọ́ 10 oṣù keje ọdún 2018, Ọọni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi Ọjájá II kede ni ita gbangba pe “... ilẹ̀ ọlọla ti Bahia de Todos os Santos, ni yóò ṣe tọka si ni ifowosi àti pe a mọ si Olú-ìlú Ilu àwọn Yorùbá ni gbogbo Amẹ́rika..."
Nínú àworan ti o wa soke, láti osi si otun: Olúkọ̀
Agba Mawo Prof. Adelson, Olúkọ̀ ti Èdè àti Àṣà Yorùbá-Ànàgó; Dọkita Arany Santana, Alákoso èto Àṣà ti
ipinlẹ̀ Bahia; Dọkita Francisco de Assis, Aṣoju Olórí
ìlú Savador; Ọba Adeyeye Ogunwusi Ojaja II, Ọọni ti Ile-ifẹ̀;
Dọkita Fábya Reis, Alákoso èto ilodi si
ẹlẹyamẹya
ti
ijọba ipinlẹ́ Bahia;
Bàbálòrìṣà Air José Sowzer, Olórí ẹsin òrìṣà ibilẹ̀ Ilé Ogodo.

Comentários
Postar um comentário