Biṣobu Desmond Tutu, olokiki ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà tó jade laye
Biṣọbu agba Desmond Tutu, olórí bíṣọ́ọ̀bù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn fẹ́ràn káàkiri agbáyé nitori ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà, fi aye silẹ lẹni aadọrun un ọdun. Aarẹ Cyril Ramaphosa ti orílẹ̀-èdè South Africa lo kede iku rẹ̀ ninu atẹjade kan to fi sita. Bẹ́ẹ̀ni, ni Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹẹ́rìndínlọ́gbọ̀n Oṣù kejìlá ọdun 2021 ni Desmond Tutu to fi dagbere faye. Gẹ́gẹ́ bíì àlùfáà aláwọ̀ dúdú pàtàkì, o di ẹni tí ó ní láti dá si ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà ni ó máa ń sọ wípé nítorí ẹ̀sìn ni òun ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà, kìí ṣe nítorí òṣèlú. Aarẹ Nelson Mandela yàn áń gẹ́gẹ́ bíi olórí àjọ àpejorò to ṣe ìwádii àwọn ìwà ọ̀daraǹ tó ṣẹlẹ̀ nígbà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa. Desmond Mpilo Tutu (7 Oṣù kẹwàá 1931 - 26 Oṣù kejìlá 2021) jẹ́ biṣọọbu Anglican kan ti South Africa ti a mọ fún iṣẹ wọ́n bi atako eléyàmẹ̀yà ati alafojusi ẹ̀tọ́ ènìyàn . O jẹ́ Bishop ti Johannesburg lati ọdún 1985 si 1986 ati lẹhinna Archbishop ti Cape Town lati 1986 si 1996, ni àwọn ọran mejeeji jẹ́ ọmọ...