Ọjọ́ oni ni Ọjọ́ Abámẹ́ta
Ẹ kú
dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ èdè àti àsà Ànàgó
Mo ki
gbogbo yin!
Ọjọ́
oni ni Ọjọ́ Abámẹ́ta, Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejìlá ọdún, abi,
gẹ́gẹ́
bí Kalẹ́ńdà ibilẹ̀ Yorùbá ṣe sọ, Ọjọ́ kejìdínlógún Ọpẹ́.
Awa ń
tẹsiwaju bọ àwọn irunmọnlẹ̀, òrìṣà ati vodun ti àwọn alálẹ̀ wa mu wa láti
ila oorun ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ni ìgbà atijọ, laarin èto òwò ẹrú agbaye.
Mo ń gbé
ni ìlú Salvador, olú-ìlú iipinlẹ Baííà ni orílẹ̀-èdè Brasili, tíi ṣé orílẹ̀-èdè
keji ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ si jùlọ agbaye lẹhin Naijiria.
Ní ìlú Salvador lọjọ́ oni, àwọn onígbàgbọ́
orìṣà àti Vodun ń bọ àwon òrìṣà ati Vodun ti daabo àwọn ojà bo.
Orúkọ temi ni Olukọ Agba Adelson de Brito ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ si Mawo
Adelson.
Mo si tún jẹ́ olori ilé-ijọsin ibilẹ̀ Òrìṣà ati Vodun ti orúkọ̀
rẹ̀ ni Hunkpamẹ Savalou Ànàgo-Vodun Sakpata-Azonsu nu Xwe ti o wa ni ìlú
Arembepe tabi ìlú Arẹ̀ańgbépẹ ìlú ti o di pàtàkì fún ìtan àwọn ọmọ dúdú ni
ipinlẹ̀ Baííà
Tẹ́ẹ bá fẹ́ gba àdúrà sì àwọn òrìṣà ilẹ̀ Oduduwa, ẹ jẹ́ ki ẹẹ́ lo èdè
abinibi àwon bàbá nla wa.
Lati igba ewe mi ti mo ń bọ latẹnu àwọn
àgbalagbà pe o ṣe pàtàkì ki ẹẹ́ lo èdè Ànàgó láti gbadura sì àwọn òrìṣà ati
irumọlẹ̀ ati Vodun ilẹ̀ atilẹba àwon alálẹ̀ wa.
Lode oni wọ́n pe èdè Ànàgó bi èdè
Yorùbá.
Lati aye atijọ́
ni Yorùbá ti ni ìgbàgbọ́ ninu ki a gba àdúrà nitori pe ohun gbogbo fẹ́
àdúrà “Ohun ti o dára fẹ́ àdúrà ki ó bà lé dára si, eyi ti kò dára
na fẹ́ àdúrà ki ó bà lé yanjú”
A
kò gbọdọ gbagbe pe lakọkọ
ni ẹẹ́ jẹ́ ki ń bọ Eṣù Ẹlẹ́gbara.
Jẹ́ ki a sọ:
Kò gbá, Laroye Eṣù
Eṣù kì í ṣùsù ọ̀na
Kò gbá, Laroye
Ago mojúbà Eṣu
Eṣu mojúbà
Ẹlẹ́gbara ajágbọn wo sì
Araketu ń sọ̀rọ̀ ṣòrò
Eṣu jinni jinni
Kò gbá, Laroye
Jẹ́ ki a gbadura si àwon Vodun Avesan ati òrìṣà Ọya àti gbogbo irunmọlẹ̀
Ìyagba ọrún fún wa ounje wa tiwa ni ọjọ́ oni ati lojoojumọ laarin ọdún to ń
bọ.
Aṣẹ!
Comentários
Postar um comentário