Christmas: Ìdí tí Bàbá Kérésì fi máà n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo
Ọpọlọpọ
gbagbọ pe Baba Keresi maa n wọṣọ ni ibamu pẹlu aàwọ̀ pupa ati funfun to wa lara
agolo nkan mimu ẹlẹrindodo Coke.
Won
ro eyi nitori pe ipolowo ọja Coca Cola ni nkan bii ọdun 1930 lo sọ Baba Keresi
di gbaju-gbaja.
O
dara bẹẹ, ṣugbọn wọn ko da Baba Keresi alaṣọ pupa ati funfun kalẹ lati polowo
Coca Cola, ṣugbọn nitori pe o n du ọja pẹlu White Rock l'ọdun 1923 ni.
Orisun
miran ni aṣọ Baba Keresi ode oni ti wa.
Ọkan lara wọn ni Saint
Nicholas. Biṣọọpu Greek ni aye atijọ, to maa n wọ aṣọ pupa ni gbogbo igba to ba
ti fẹ ẹ fun awọn alaini ni ẹbun, paapa awọn ọmọde.
Ìtàn miran lati ọwọ oṣere
Netherlands, Sinterklas, to tun dale Saint Nicholas, to gbajumọ laarin awọn
olowo ni New York, bi i Washington Irving ati Clement Clark Moore ni nkan bi
ọdun 1800.
Awọn mejeeji gbiyanju
lati sọ Aisun alẹ Keresimesi di nkan ti gbogbo eniyan yoo wa lori ibusun wọn
lati sun, dipo ayẹyẹ ati ariya ita gbangba.
Ọgbẹni
Moore jẹ ọ̀kan lara awọn to da Baba Keresimesi ti Amẹrika silẹ - ẹni mimọ to
maa n wọ aṣọ pupa, ti yoo si maa fun gbogbo eniyan ni ẹbun, boya wọn fẹ tabi
wọn ko fẹ ẹ.
Ta a ni Baba Keresi gan
an gan?
A
le tọ ipasẹ Baba Keresi lọ si ọdọ Biṣọọpu Greek, Nicholas.
Olukọtan
kan ni Fasiti Manitoba, Gerry Bowler, ṣalaye pe nitori pe Ẹni Ọwọ Nicholas maa
n pin ẹbun fun awọn eniyan, ni wọn ba bẹrẹ sii ri gẹgẹ bi baba-isalẹ awọn ọmọde
ati onidan to maa n fun nii ni nkan.
Ṣugbọn,
ipolowo ọja lo mu ki Baba Keresimesi ode-oni o gbajumọ.
Ni
nkan bi ọdun 1820, ipolowo fun ẹbun ọdun Keresimesi bẹrẹ si ni tan kiri
orilẹ-ede Amẹrika, nigba ti yoo si fi di ọdun 1940, Baba Keresi naa ti bẹrẹ si
ni farahan daada ninu ipolowo ọja.
Bi
ififunni lasiko Keresi ṣe bẹrẹ niyi.
Orisun ati Aworan: https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-50910234 ( 24 Ọpẹ́ 2021)
Comentários
Postar um comentário