Postagens

Mostrando postagens de agosto, 2022

Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa keji

Imagem
  Gẹgẹbi ọba, ó lágbára gan o si ni igboyà, ó máa lọ ko ijà kaakiri agbegbe yẹn. Ó fẹ́ràn lati maa fi agbára rẹ̀ han àwọn ènìyàn. Ìtàn sọ fún wa pé ni igba kan, Ṣàngó lo da ìjà silẹ̀ láàárín àwọn ìjòyè meji kan ni ìlú rẹ̀. Ikórìíra dá dá dá sí í pọ̀ débi pé ọ̀kan pa èkeji. Ọ̀pọlọ́pọ̀ àwọn olugbe Ọ̀yọ ri ohun buburu ti ọba náà ti ṣe lori àwọn ọkunrin meji yìí. Nitori idi eyi wọ́n dide ọ̀tẹ̀ si aláde. Iye eeiyan ti alaifẹ́ si ọ̀ba náà dagba gidi gan an to fa rúdurùdu wa ti mbẹ ni ìlú Ọ̀yọ. Nikẹhin, Ṣàngó ri agbára iṣelu ijọba tirẹ̀ padanu patapata mọ. Koda ó kò ri ilé duro tabi ri ènìyàn lati tù u ninu. Itan sọ fún wa pé Ṣàngó ro´nu ara rẹ̀ gan titi kò ri ohun kankan ti o le ṣe lati yanju ipo rẹ̀, ó wa yà sì ìdí igi àyàn kan. Ọba náà pokunso. Ibi naa eiyití ẹmí Sàngó kuro ninu ilé aye lati lọ sì ọ̀dọ̀ Oduduwa, o wà nítòsí ìlú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kosò, ti o wa kò jinna si Ọ̀yọ. Lati igba náà ni àwọn ọ̀tá Ṣàngó sì wípè “Ọba sọ” l...

Ògún Lakaye Osìn imọlẹ̀

Imagem
Ẹ ku deedee asiko yìí eyin ọmọ Ànàgó atata ! Ṣe alaafia ni? Ọjọ́ oni ni ọjọ́ ì ṣẹ́ gun ni ilẹ̀ àwa ọmọ Yoruba atata, Ní  ọjọ́ ìṣẹ́gun a ń b ọ́ Òrìṣà Ògún Ògún yè, pàtàkì ori Láàárin gbogbo iranṣe Olodumare! Orúkọ̀ temi ni Olukọ Agba Adelson de Brito ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ sì Mawo Adelson. Ọmọ ẹya Ànàgó ni mi,   ọmọ Oduduwa ni mi. Mo ki gbogbo ọmo ìyá Yorùbá kaakiri agbaye. Ògún ni òrìṣà ìbílẹ̀ ti daabo àwọn jagunjagun, àwọn ọdẹ, àwọn alágbẹ̀dẹ , àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àti àwọn awakọ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá lè búra láti sọ òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ nípa “fi ẹnu kò irin kan ní orúkọ Ògún.” Àwon awakọ̀ gbe amuleto Ògún lati dena ijamba ọkọ̀.  Ní ìlú wa lode oni a n bọ Ògún ni olúkúlùkù ilé ẹ̀sìn ìbílẹ̀ òrìṣà ti a ń pé ni Kandọnbilẹ́ (Candomblé). Mo tún j ẹ́ olori ẹsin ibilẹ̀ vodun kan lati il ẹ̀ ij ọba atij ọ́ Dahomy ti a ń pé ni Jeje. Ninu ẹsin Dahomey yìí, Gu ni vodun ti ogun ati ọlọrun alabojuto ti àwọn alagbẹdẹ ati à...

Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa kini

Imagem
  Ni ode oni, wọ́n ń sin àwọn òrìṣà Oduduwa lágbàáyé, paapaa ni àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Af´rika bii Nàìjíríà, Bẹnin ati, Togo, bẹ́ẹ̀ ni lára àwọn orílẹ̀-èdè mii, bii Amẹrika, Kuba, Brasili ati àwọn ìlẹ̀ kaakiri Erèkúsú Karibian. Àwọn onigbagbọ ni àwọn òrìṣà wọ̀nyí gẹgẹ bi Ọlọ́run tiwọn. Lara Òrìṣà náà a ni Èṣù, Ogun, Ọbàtálá, Yemọja, Ọ̀ṣun, ati Ṣàngó. Ó ṣeni láàánú pé àwọn Ànàgó (àwọn Yorùbá tó wà ní Brasili) ti ode oni kò lè kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn igbesiaye àwọn èèyàn tó di òrìṣà wọ̀nyí latọwọ́ àwọn baba ńlá wa lèdè abibnibi wa. Nitori ipó aiṣe deede wọ́n làwujọ́ ti ilẹ̀ yìí lakoko èto ẹrú, wọ́n kò le ṣeto àwọn ilé-ìwé lati kọ àwọn ọmọ ati iran wọn ni èdè Ànàgó gẹgẹbi èdè ti wọ́n le lo ninu ohun lojoojumọ wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, nitori iṣẹ́ takuntakun ti àwọn olori ijọsin òrìṣà ni aye atijọ́ wọ́n lr ipamọ àwọn orin ati àwon gbólóhùn ọ̀rọ̀ atilẹba àwọn wa, a ń tẹsiwaju lo àwọn ilana ijọsin abinibi òrìṣà lati ìgbà òwò ẹrú titi ode oni.  Àwa, ọmọ  Ànà...