Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa keji
Gẹgẹbi ọba, ó lágbára gan o si ni igboyà, ó máa lọ ko ijà kaakiri agbegbe yẹn. Ó fẹ́ràn lati maa fi agbára rẹ̀ han àwọn ènìyàn. Ìtàn sọ fún wa pé ni igba kan, Ṣàngó lo da ìjà silẹ̀ láàárín àwọn ìjòyè meji kan ni ìlú rẹ̀. Ikórìíra dá dá dá sí í pọ̀ débi pé ọ̀kan pa èkeji. Ọ̀pọlọ́pọ̀ àwọn olugbe Ọ̀yọ ri ohun buburu ti ọba náà ti ṣe lori àwọn ọkunrin meji yìí. Nitori idi eyi wọ́n dide ọ̀tẹ̀ si aláde. Iye eeiyan ti alaifẹ́ si ọ̀ba náà dagba gidi gan an to fa rúdurùdu wa ti mbẹ ni ìlú Ọ̀yọ. Nikẹhin, Ṣàngó ri agbára iṣelu ijọba tirẹ̀ padanu patapata mọ. Koda ó kò ri ilé duro tabi ri ènìyàn lati tù u ninu. Itan sọ fún wa pé Ṣàngó ro´nu ara rẹ̀ gan titi kò ri ohun kankan ti o le ṣe lati yanju ipo rẹ̀, ó wa yà sì ìdí igi àyàn kan. Ọba náà pokunso. Ibi naa eiyití ẹmí Sàngó kuro ninu ilé aye lati lọ sì ọ̀dọ̀ Oduduwa, o wà nítòsí ìlú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kosò, ti o wa kò jinna si Ọ̀yọ. Lati igba náà ni àwọn ọ̀tá Ṣàngó sì wípè “Ọba sọ” l´o gba jakejado gbogbo agbegbe ilẹ̀Yorùbá. Ṣùgbọ́n, àwọn olúfẹ wọ́n fesi nipa wi wipe " Ọba kò so”.
Lati ìwé “Àṣà àti Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá”, Dọ́kítà Olu Daramola àti Dọ́kítà Adebayọ Jeje

Comentários
Postar um comentário