Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa kini
Ni ode oni, wọ́n ń sin àwọn òrìṣà Oduduwa lágbàáyé, paapaa ni àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Af´rika bii Nàìjíríà, Bẹnin ati, Togo, bẹ́ẹ̀ ni lára àwọn orílẹ̀-èdè mii, bii Amẹrika, Kuba, Brasili ati àwọn ìlẹ̀ kaakiri Erèkúsú Karibian. Àwọn onigbagbọ ni àwọn òrìṣà wọ̀nyí gẹgẹ bi Ọlọ́run tiwọn. Lara Òrìṣà náà a ni Èṣù, Ogun, Ọbàtálá, Yemọja, Ọ̀ṣun, ati Ṣàngó. Ó ṣeni láàánú pé àwọn Ànàgó (àwọn Yorùbá tó wà ní Brasili) ti ode oni kò lè kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn igbesiaye àwọn èèyàn tó di òrìṣà wọ̀nyí latọwọ́ àwọn baba ńlá wa lèdè abibnibi wa. Nitori ipó aiṣe deede wọ́n làwujọ́ ti ilẹ̀ yìí lakoko èto ẹrú, wọ́n kò le ṣeto àwọn ilé-ìwé lati kọ àwọn ọmọ ati iran wọn ni èdè Ànàgó gẹgẹbi èdè ti wọ́n le lo ninu ohun lojoojumọ wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, nitori iṣẹ́ takuntakun ti àwọn olori ijọsin òrìṣà ni aye atijọ́ wọ́n lr ipamọ àwọn orin ati àwon gbólóhùn ọ̀rọ̀ atilẹba àwọn wa, a ń tẹsiwaju lo àwọn ilana ijọsin abinibi òrìṣà lati ìgbà òwò ẹrú titi ode oni. Àwa, ọmọ Ànàgó tí o di olúsọ èdè Yorùbá-Nàgó, lè kẹkọ nipa ọ̀pọlọ́pọ̀ ohun ti igbesiaye àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti di eeyian mimọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá. Loni a yóò kọ́ yin ṣ díẹ̀ nipa igbesiaye ti Ṣàngó nigba ti òrìṣà yìí wa gbé ninu ilé aye gẹ́gẹ́ bi ọba ni ilẹ̀ Yorùbá.Nínú ìwé “Àṣà àti Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá”, Dọ́kítà Olu Daramola àti Dọ́kítà Adebayọ Jeje sọ ìtàn òrìṣà Ṣàngó, a sì mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àsọyé rẹ̀ tí a ń tẹnu mọ́ nígbà àdúrà wa.Ṣàngó jẹ́ òrìṣà kan ti ìtan rẹ̀ kun fún ohun iyalẹnu.Nígbà tí o wa l´áàyè, àwọn ènìyàn l´agbọ pé ó ní agbára lori àrá, nítorí èyí ó di òrìṣà ààrá. Ni igba laelae, ó jẹ́ ọba l´ode Ọ̀yọ ti jẹ́ Ẹ̀yeọ́ tabi Katunga ni àkókò náà.Ìtàn sọ nipa rẹ̀ pé ọmọ Ọ̀rányàn ni Ṣàngó i ṣe àti pe Ọya, Ọ̀ṣun ati Ọba jẹ́ Iyawo rẹ̀.
Ipari Apa kini

Comentários
Postar um comentário