Ògún Lakaye Osìn imọlẹ̀


Ẹ ku deedee asiko yìí eyin ọmọ Ànàgó atata!

Ṣe alaafia ni?

Ọjọ́ oni ni ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ilẹ̀ àwa ọmọ Yoruba atata,

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun a ń bọ́ Òrìṣà Ògún

Ògún yè, pàtàkì ori Láàárin gbogbo iranṣe Olodumare!

Orúkọ̀ temi ni Olukọ Agba Adelson de Brito ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ sì Mawo Adelson.

Ọmọ ẹya Ànàgó ni mi,  ọmọ Oduduwa ni mi.

Mo ki gbogbo ọmo ìyá Yorùbá kaakiri agbaye.

Ògún ni òrìṣà ìbílẹ̀ ti daabo àwọn jagunjagun, àwọn ọdẹ, àwọn alágbẹ̀dẹ , àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àti àwọn awakọ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá lè búra láti sọ òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ nípa “fi ẹnu kò irin kan ní orúkọ Ògún.” Àwon awakọ̀ gbe amuleto Ògún lati dena ijamba ọkọ̀. 

Ní ìlú wa lode oni a n bọ Ògún ni olúkúlùkù ilé ẹ̀sìn ìbílẹ̀ òrìṣà ti a ń pé ni Kandọnbilẹ́ (Candomblé).

Mo tún jẹ́ olori ẹsin ibilẹ̀ vodun kan lati ilẹ̀ ijọba atijọ́ Dahomy ti a ń pé ni Jeje. Ninu ẹsin Dahomey yìí, Gu ni vodun ti ogun ati ọlọrun alabojuto ti àwọn alagbẹdẹ ati àwọn oniṣọnà. A rán a si aiye lati sọ ọ di ibi ti o dara fún àwọn ènìyàn lati gbe, ko si tii pari iṣẹ yii. Ìdí nìyí tí a fi ń kọ orin kan tí ó rán wa létí iṣẹ́ pàtàkì yìí tí Ògún dá sí: ìṣàwárí ìgbà gbogbo fún ìdàgbàsókè ipò ayé wa. Jẹ́ ki a ń korin:

Ògún ajo

mariwo

Alakoro ajo

mariwo

Ògún pa le pa lọ̀na

Ògún ajo

mariwo

Ẹlẹ́ ki fí ẹ̀jẹ̀ wẹ̀

Ògún yè, pàtàkì ori òrìṣà!

Aworan Alabi Ogundepo

 


 

Comentários

Postagens mais visitadas deste blog

Ẹ kaabọ̀ si Kilombo Kingoma náà, akọkọ ilẹ̀ ibilẹ̀ Afirika ni okeere

Ìtàn òrìṣà Ṣàngó ti a ranti nínú ìjọsìn wa apa keji