Ẹ kaabọ̀ si Kilombo Kingoma náà, akọkọ ilẹ̀ ibilẹ̀ Afirika ni okeere
Ìlú wo lo gbọ Yorùbá jùlọ ni orílẹ̀èdè
Brasil?
Ìlú náà
ti ọ̀pọ̀ ènìyàn ń pé ní ìlú
Bahia.
Orúkọ̀
mi ni Adelson Adewale de Brito ti ọpọlọpọ ènìyàn mọ̀ si Ọ̀mọ̀wé Adelson tabi Mọ̀wé
Adelson tabi Mawo Adelson.
Mo
ki gbogbo ilé,
Mo
ki awon baba nla wá, Mo ki, awon Ìyá nlá wa.
Oduduwa
Mo juba!
Mo
ki awon omo iya fún ajoyo yìí. Mo bẹ Èṣù Ẹlẹ́gbára, ki ó fún wa ni ọ̀na ti o dará, ti o si ye kooro. Jẹ́ ki a ki Èṣù
ni ṣaaju ki a sọ̀rọ̀ nipa ohunkohun ninu èto wa loni:
Ago, Mo júbà Èṣù,Èṣù, Mo júbà
Mo ki Ẹlẹ́gbára ti won ri
ajagbọn wa ti o farasin
Araketu náà ti o ń sọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀
Èṣù jinnijinni
Kò gba
Laroye!
Ni ọjọ́ mọkandinlogun
oṣù Ẹrẹ́nà yìí lára
abẹwo ìgbà keji si orílẹ̀-èdè Brasil, Ọọ̀ni Ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja
keji wa si ìlú Lauro de Freitas ni ipinlẹ̀ Bahia lati sọ̀ Kilombo Kingoma náà
lelẹ̀ gẹgẹ bi akọkọ ilẹ̀ ibilẹ̀ Afirika
ni okeere.
Ni oruko temi ati loruko gbogbo ọmọ ìlú Lauro de Freitas ati ọmọ Kilombo Kingoma mo ki Baba Ọọni ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji
Kabiesi oooooo.
Ki Ade pe Lori, Baba
Ki iru kere pe lowo yin, Baba
Ki bata pe lese,
Ki
aase pe lenu yin, Baba
Bàbá, Mo ki yin Ẹ káàbọ̀ pẹ̀lu inudidun nitori pe Mo lo
èdè àwọn Bàbá nlá wa lati ki yin “Ẹ́ káàbọ̀” si ìlú Bahia.
Ilu Bahia Olu-ìlú Yorùbá fun gbogbo Amerika.
Ìlú Bahia náà jẹ́ ìlú ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ jùlọ
lagbaye lẹ́hìn Afrika.
Ni ọjọ́ kewa, oṣù kẹfà, ọdún 2018 lára abẹwo si orílẹ̀-èdè
Brasil, Ọọ̀ni Ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji wa si ìlú Salvador
lati sọ ọ́ ń fi ipinlẹ̀ Baííà lelẹ̀ gẹgẹ̀ bi Olú-ìlú
Yorùbá fún gbogbo àwọn Amẹ́rika.
Njẹ o mọ̀ wípè ni ìgbà atijọ́, làkókò òwò ẹrú ni ìlú
yìí, ọpọlọpọ ọmọ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú lò èdè Ànàgó gẹ́gẹ́bí “língua franca” fún
ibanisọ̀rọ̀ láàárín ara wọn?
Bẹ́ẹ̀ni, nitori agbára àṣà Ànàgó ni ìlú yìí, ọpọ́lọpọ̀ ọmọ
ilẹ̀ Afirirka laibikita ẹya wọn tún ti lo èdè Ànàgó lára ohun ojoójumọ̀ wọn
kaakiri agbegbe ìlú náà.
Nitori wipe ni ìlú yìí wọn ńpe àwọn aláwọ̀ dúdú ti sọ̀
lèdè Yorùbá ati ti kuro ninu agbegbe iwọ ọọ̀run ilẹ̀ Afrika "Ànàgó" wọn
tún npè èdè wọn náà “èdè Ànàgó” abi “Nàgó”.
Lode oni a ń pe Èdè Ànàgó ni Èdè Yorùbá. A ri wípè
kaakiri agbaye ni wọn ka ilẹ̀ Brasil bi orilẹ̀èdè kan pàtàkì ti wọn ti n sọ̀
èdè Yorùbá ti wọn si tun n ṣe ẹsin ibilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n o ṣe ni laanu pe èdè
Yorùbá ti di èdè ajeji ni ilẹ̀ Brasil yìí kanna. Fun apẹrẹ, bi o ba fẹ kọ èdè
faranse, èdè italian, èdè japanese, èdè payaan (Spanish) a.b.b.l., ati ri olukọ̀ tabi ilé ẹ̀kọ́ kò ṣoro, ṣùgbọ́n bi o
ba fẹ kọ̀ èdè Yorùbá . ati ri olukọ tabi ilé ẹ̀kọ́, gidi a di ọran! Loju temi ẹlẹyamẹya
ni eleyi.
Wọn kò gbe èdè Yorùbá si ipo yìí ati ẹyẹ ti o to si i.
Mo fẹ gba aanfani asiko yìí, bere iranlọ̀wọ́ kabiyesi
lati um èdè Yorùbá pada si ipo to yẹ
làáàrin àwọn èdè ilẹ̀ Brasil. Jẹ́ ki a gbe Yorùbá pada si ipo èdè ti àwọn ọmọ
Ànàgó lo nipa ohun lójoojúmọ̀ wọn. Pẹlu agbara Eledumare

Comentários
Postar um comentário