Irohin nipa Orin Òrìṣà 1
Ẹ ku deedee asiko yìí eyin ọmọ Ànàgó atata!
O ma tọjọ́ mẹ́ta o!
Ṣe o mọ̀ wípè ni aye atijọ́, làkókò oko ẹrú ni ìlú yi, àwọn ọmọ
káàrò-oòjíire lò èdè kanna fún ibaraẹninsọ̀rọ̀ laarin ara wọn?
Wọn a pè ara wọn “Ànàgó”, àwọn ènìyàn miran tún pè èdè wọn “èdè Ànàgó” abi “èdè Nàgó”, abi “Nàgó.
A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé
pe o ṣe pàtàkì ki a lugbadi ohun ti o já kiri orílẹ̀-èdè
agbaye bayii o, amọ́n, ẹ jẹ́ ki a pa ofin imọtoto mọ, ki a sì
yàgò fún ipéjopọ̀ ti o ba jù iye ti ijọba ipinlẹ̀ sọ lọ, aabo àwọn irunmalẹ ti ilẹ̀ Oduduwa yoo daju
lori gbogbo wa o.
Eyin ọmọ mi olufẹ, Mo wa de níbí yìí loni nitori pe mo fẹ́ sọ nipa
orin Òrìṣà.
Ni Ọjọ́ Rírú to kọja ni, wọ́n a ń pe
mi sì ayẹyẹ
ibimọ Òrìṣà túntún
kan.
A korin ọpọlọpọ àwọn orin fún iyin Òrìṣà Oṣóòsi, ṣùgbọ́n, o kò yẹ mi ohun ti wọ́n ń
korin.
Eyi ti ṣe
aniyan mi nigbagbogbo laarin igbesi aye mi.
Mo bòwò
fún iṣẹ ti àwọn babanla wa ṣiṣẹ lati fún wa àwọn ijogun ti wa gba
latọdọ wọ́n. Nitori eyi mo ń ro pe ẹ jẹ́ ki a ipamọ̀ èdè ati àṣà wọn
gidigidi.
O ṣe pàtàkì
pupọ pe ki a ṣetọju èdè ati àṣà Yorùbá gẹgẹbi afara ti o so gbogbo àwọn ọmọ
Yoruba kaakiri agbaye, gẹgẹ bi ẹda kan ṣoṣo abi ọmọ iya kan ṣoṣo.
Gẹgẹ bi Mo sọ, mo wa
de lati sọ nipa òrìṣà. Mo tún sọ pe mo fẹ ṣọ̀rọ̀ nipa òrìṣà Oṣóòsí, ṣùgbọ́n, bi ọmọ Òrìṣà ati Vodun, o daniloju pe a kò le sọ nipa òrìṣa eyikeyi
laisi ikini si Òrìṣa Eṣù,
Kò gba,
Laróyè, Èṣù
Eṣù kì í ṣùsù ọ̀nà
Kò gba, Laróyè
1.
Ẹ
Barabo Ẹ mo
júbà àwa kò ṣé
Ẹ
Barabo Ẹ mo
júbà, ọmọdé kọ ẹkọ,
Ki Barabo Ẹ mo júbà,
Ẹlẹgbára
Èṣú kò ṣé (2x)
2.
Bará O bẹẹbẹẹ Tiriri l´ ọ̀nà
Èṣù Tiriri
Bará O bẹẹbẹẹ Tiriri l´ ọ̀nà (2x)
3.
Àgò ńbọ ńbọ
Laróyè
Àgò ńbọ ńbọ
Laróyè

Comentários
Postar um comentário