Postagens

Oni ni ajọdún ti Ọọni Ilé-Ifẹ̀ náá ikede ìlú Bahia gẹgẹbi Olú-ìlú Yorùbá ti gbogbo àwọn Amẹ́rikà

Imagem
  Lára abẹwo si orílẹ̀-èdè Brasíìlì ni o ṣù keje, ọdún 2018, Ọọni ile-Ifẹ náà, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji ni: “... àwọn ọmọ Yorùbá to wa kaakiri igun mẹrẹrin agbaye ko gbọdọ sọ ami idanimọ wọn nu, nitori ọmọ iya kan naa ni gbogbo awọn ọmọ Oodua bii Itsekiri, Edo, Ga, Anago, Igala, Lucumi, Tapa, ati Yoruba ti orisun wọn si wa ni ilu Ile Ifẹ...” Àwọn iran ti àwọn Ànàgó ni ode oni ìlú Brasílì kò le lo èdè náà fún àwọn ohun iṣe ti ojojumọ wọn. Sibẹsibẹ, àwọn orin, ijó, ìtan aye atijọ́, ounjẹ ati ẹ̀sin ń ṣiṣe ni ọpọ àgbègbé kaakiri orílẹ̀-èdè náà.   “... àwọn ọmọ Yorùbá to wa kaakiri igun mẹrẹrin agbaye ko gbọdọ sọ ami idanimọ wọn nu, nitori ọmọ iya kan naa ni gbogbo awọn ọmọ Oodua bii Itsekiri, Edo, Ga, Anago, Igala, Lucumi, Tapa, ati Yoruba ti orisun wọn si wa ni ilu Ile Ifẹ...” Àwọn iran ti àwọn Ànàgó ni ode oni ìlú Brasílì kò le lo èdè náà fún àwọn ohun iṣe ti ojojumọ wọn. Sibẹsibẹ, àwọn orin, ijó, ìtan aye atijọ́, ounjẹ ati ẹ̀sin ń ṣiṣe ni ọpọ àgbègbé kaak...

Oba Lamidi Adeyemi ti jáde láyé!

Imagem
  BBC Yoruba ti kan si Aafin Oyo fun ẹkunrẹrẹ lori iku Ọba Lamidi Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo. Iroyin naa tẹ wa lọwọ ni yajoyajo lowurọ yii to sọ pe Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti lọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ lajule ọrun. "Gbogbo eto aṣa ati iṣẹẹṣe ti bẹrẹ bayii ni Aafin"!  Ki lo n ṣẹlẹ l'Aafin Alaafin lọwọ lowurọ yii? Ọmọba ni Aafin Oyo sọ fun BBC Yoruba pe kete ti wọn rii pe baba ti re alakeji ni ilana aṣa ati iṣẹṣe ti bẹrẹ l'Aafin ni pẹrẹwu. "Wọn ti bẹrẹ aṣa ati iṣẹṣe bayii. A ni ki ni yoo tun ṣẹlẹ bi ojumọ ba ti mọ ni Aafin, ọmọba ni "ṣe ẹ mọ pe ọmọde lemi, awọn agbaagba si wa atawọn alaṣẹ ni Aafin torinaa emi o le sọ". Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà Ni oru ọganjọ ti a kọkọ bẹrẹ si ni gbọ fiinfiin ni BBC Yoruba ti tara ṣaṣa kan si afin ti ọkan lara awọn ọmọ aafin rẹ si fi da wa loju pe Baba ti lọ. Wiwadii yii kan ṣe kongẹ asiko ti ọmọ wọn maa n ji fun saari, ni ...

Biṣobu Desmond Tutu, olokiki ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà tó jade laye

Imagem
Biṣọbu agba Desmond Tutu, olórí bíṣọ́ọ̀bù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn fẹ́ràn káàkiri agbáyé nitori ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà, fi aye silẹ lẹni aadọrun un ọdun. Aarẹ Cyril Ramaphosa ti orílẹ̀-èdè South Africa lo kede iku rẹ̀ ninu atẹjade kan to fi sita. Bẹ́ẹ̀ni, ni Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹẹ́rìndínlọ́gbọ̀n Oṣù kejìlá ọdun 2021 ni Desmond Tutu to fi dagbere faye. Gẹ́gẹ́ bíì àlùfáà aláwọ̀ dúdú pàtàkì, o di ẹni tí ó ní láti dá si ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà ni ó máa ń sọ wípé nítorí ẹ̀sìn ni òun ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà, kìí ṣe nítorí òṣèlú. Aarẹ Nelson Mandela yàn áń gẹ́gẹ́ bíi olórí àjọ àpejorò to ṣe ìwádii àwọn ìwà ọ̀daraǹ tó ṣẹlẹ̀ nígbà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa. Desmond Mpilo Tutu (7 Oṣù kẹwàá 1931 - 26 Oṣù kejìlá 2021) jẹ́ biṣọọbu Anglican kan ti South Africa ti a mọ fún iṣẹ wọ́n bi atako eléyàmẹ̀yà  ati alafojusi ẹ̀tọ́ ènìyàn . O jẹ́ Bishop ti Johannesburg lati ọdún 1985 si 1986 ati lẹhinna Archbishop ti Cape Town lati 1986 si 1996, ni àwọn ọran mejeeji jẹ́ ọmọ...

Christmas: Ìdí tí Bàbá Kérésì fi máà n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo

Imagem
  Ọpọlọpọ gbagbọ pe Baba Keresi maa n wọṣọ ni ibamu pẹlu aàwọ̀ pupa ati funfun to wa lara agolo nkan mimu ẹlẹrindodo Coke. Won ro eyi nitori pe ipolowo ọja Coca Cola ni nkan bii ọdun 1930 lo sọ Baba Keresi di gbaju-gbaja. O dara bẹẹ, ṣugbọn wọn ko da Baba Keresi alaṣọ pupa ati funfun kalẹ lati polowo Coca Cola, ṣugbọn nitori pe o n du ọja pẹlu White Rock l'ọdun 1923 ni. Orisun miran ni aṣọ Baba Keresi ode oni ti wa. Ọkan lara wọn ni Saint Nicholas. Biṣọọpu Greek ni aye atijọ, to maa n wọ aṣọ pupa ni gbogbo igba to ba ti fẹ ẹ fun awọn alaini ni ẹbun, paapa awọn ọmọde. Ìtàn miran lati ọwọ oṣere Netherlands, Sinterklas, to tun dale Saint Nicholas, to gbajumọ laarin awọn olowo ni New York, bi i Washington Irving ati Clement Clark Moore ni nkan bi ọdun 1800. Awọn mejeeji gbiyanju lati sọ Aisun alẹ Keresimesi di nkan ti gbogbo eniyan yoo wa lori ibusun wọn lati sun, dipo ayẹyẹ ati ariya ita gbangba. Ọgbẹni Moore jẹ ọ̀kan lara awọn to da Baba Keresimesi ti Amẹrika silẹ - ẹni...

Ọjọ́ oni ni Ọjọ́ Abámẹ́ta

Imagem
Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ èdè àti àsà Ànàgó Mo ki gbogbo yin! Ọjọ́ oni ni Ọjọ́ Abámẹ́ta, Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejìlá ọdún, abi, gẹ́gẹ́ bí Kalẹ́ńdà ibilẹ̀ Yorùbá ṣe sọ, Ọjọ́ kejìdínlógún Ọpẹ́. Awa ń tẹsiwaju bọ àwọn irunmọnlẹ̀, òrìṣà ati vodun ti àwọn alálẹ̀ wa mu wa láti ila oorun ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ni ìgbà atijọ, laarin èto òwò ẹrú agbaye. Mo ń gbé ni ìlú Salvador, olú-ìlú iipinlẹ Baííà ni orílẹ̀-èdè Brasili, tíi ṣé orílẹ̀-èdè keji ti àwọn aláwọ̀ dúdú pọ̀ si jùlọ agbaye lẹhin Naijiria.   Ní ìlú Salvador lọjọ́ oni, àwọn onígbàgbọ́ orìṣà àti Vodun ń bọ àwon òrìṣà ati Vodun ti daabo àwọn ojà bo. Orúkọ temi ni Olukọ Agba Adelson de Brito ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ si Mawo Adelson. Mo si tún jẹ́ olori ilé-ijọsin ibilẹ̀ Òrìṣà ati Vodun ti orúkọ̀ rẹ̀ ni Hunkpamẹ Savalou Ànàgo-Vodun Sakpata-Azonsu nu Xwe ti o wa ni ìlú Arembepe tabi ìlú Arẹ̀ańgbépẹ ìlú ti o di pàtàkì fún ìtan àwọn ọmọ dúdú ni ipinlẹ̀ Baííà Tẹ́ẹ bá f...

Ògún Lakaye Osìn imọlẹ̀

Imagem
  Ẹ ku deedee asiko yìí eyin ọmọ Ànàgó atata. Ṣe alaafia ni? Ọjọ́ oni ni ọjọ́ ì ṣ ẹ́ gun ni ilẹ̀ àwa ọmọ Yoruba atata, Ní  ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ìlú wa a ń b ọ́ Òrìṣà Ògún Ògún yè, pàtàkì ori òrìṣà! Orúkọ̀ temi ni Olukọ Agba Adelson de Brito ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ sì Mawo Adelson. Ọmọ Oduduwa ni mi. Mo ki gbogbo ọmo ìyá Yorùbá kaakiri agbaye. Ògún ni òrìṣà ìbílẹ̀ àwọn jagunjagun, ọdẹ, alágbẹ̀dẹ , onímọ̀ ẹ̀rọ, àti awakọ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá lè búra láti sọ òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ nípa “fi ẹnu kò irin kan ní orúkọ Ògún.” Àwon awakọ̀ gbe amuleto Ògún lati dena ijamba ọkọ̀.   Ní ìlú wa lode oni a n bọ Ògún ni olúkúlùkù ilé ẹ̀sìn ìbílẹ̀ òrìṣà ti a ń pé ni Kandọnbilẹ́ (Candomblé). Mo tún j ẹ́ olori ẹsin ibilẹ̀ vodun kan lati il ẹ̀ ij ọba atij ọ́ Dahomy ti a ń pé ni Jeje. Ninu ẹsin Dahomey yìí, Gu ni vodun ti ogun ati ọlọrun alabojuto ti àwọn alagbẹdẹ ati àwọn oniṣọnà. A rán a si aiye lati sọ ọ di ibi ti...

Yoruba NationYoruba Nation One million man march: Àwọn tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation ní IPOB kò ṣiṣẹ pọ̀ pẹ̀lú àwọn

Imagem
  Àwọn to n ṣagbatẹru idasilẹ Yoruba nation ti ṣalaye fun ijọba Naijiria pe ẹgbẹ ajijagbara IPOB kọ lo ṣe agbekalẹ ifẹhonuhan tawọn n ṣe ni olu ileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN lorilẹede Amẹrika. Eyi ni esi wọn si atẹjade ijọba apapọ to kilọ pe wọn o gbọdọ ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra, IPOB. Lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii lawọn ajijagbara fun Yoruba Nation atawọn ẹya mii naa ni Naijiria ti n ṣe iwọde ni olu ileeṣẹ ajọ UN niluu New York lorilẹede Amẹrika. Iwọde yii wa jẹ asiko kan naa pẹlu apejọ ajọ UN nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn olori orilẹede agbaye mii yoo ti sọrọ apilẹkọ. Alaga ẹgbẹ NINAS to jẹ akojọpọ awọn ẹgbẹ ajijagbara ni Naijiria, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni awọn n ṣe iwọde niwaju olu ileeṣẹ ajọ UN lati le jẹki gbogbo aye mọ bi awọn darandaran ṣe n fi ẹmi awọn eeyan ṣofo lapa Guusu ati arin gbungbun orilẹede Naijiria Ijoba Naijiria ni idi ti awọn se n lọgun bẹẹ ni pe labẹ ofin awọn ka IPOB gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi to n da omi a...